Categories
Ìròyìn

Òfin Máa Ṣègbè Fún Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn Láti Fọwọ́ Ṣùkún Òfin Mú Ẹnikẹ́ni Tí ó Bá Gbẹ́ná Wojú Òfin – Amòfin Àgbà

YBTC Yorùbá- Èkó, Ogun àti Ìpínlẹ̀ Ekiti ni ó ń léwájú nínú ètò fífi òfin de ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn tí àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí.

Amòfin Àgbà ìpínlẹ̀ Ekiti tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́ ìpínlẹ̀ náà, Wale Fapohunda tí ó fi ọ̀rọ̀ yìí tó àwọn oníròyìn létí ní ọjọ́ àìkú tún sọ wípé àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn náà ma ní agbára láti fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú ẹnikẹ́ni tí ó bá lú fín.

Fapohunda sọ ní ọjọ́ àìkú wípé àwọn Amòfin Àgbà àti Mínísítà fún ètò Ìdájọ́ gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà yóò