Categories
Eré Ìdárayà

Manchester City Pegedé Fún Ìpele Karùn-ún Nínú Ìdíje FA Cup

YBTC Yorùbá- Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Manchester City ti pegedé fún ìpele karùn-ún nínú ìdíje FA Cup bí wọ́n ṣe kán Ikọ̀ Fulham lẹ́yìn ní ayọ̀ mẹ́rin sí òdo ní ilé wọn ní Etihad ní ọjọ́ àìkú.

Ńìkan bí ìṣẹ́jú mẹ́fà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ni Tim Ream gba káàdì pupa tí afọnfèèrè sì le jàre kúrò ní ori pápá nígbà tí ó ṣe àṣemáṣe nípa gúngun ẹ̀yìn Gabriel Jesus nínú ìlà ṣee jẹ́jẹ́.