Categories
Uncategorized

Alága Àjọ INEC Fẹsẹ̀fẹ Ní Ìpínlẹ̀ Imo Bí Àwọn Jàndùkú Ṣe Yabo Ìyàrá Ìkàbò

YBTC Yorùbá-Hílàhílo bẹ́ sílẹ̀ níbi tí Àjọ tí ó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Independent National Electoral Commission, (INEC) tí ń ka àtúndì Ìbò aṣojú ṣòfin ti ìjọba ìbílẹ̀ Orlu/Orsu/Òru ti ìpínlẹ̀ Imo bí àwọn jàndùkú ṣe yabo Ìyàrá ìkàbò náà.

Àwọn Jàndùkú náà na Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Ìyàrá ìkàbò náà kí wọ́n tó ya lọ sí ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ INEC wàá, tí wọ́n sì da gbogbo ètò náà rú.

Yàtò sí wípé àwọn Jàndùkú náà tí wọn kò sọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fu fà ìwé èsì ìdìbò ya, wọ́n ní ètò ìdìbò náà ti ní kọ́lu kọ́ha nínú.