Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Èmi Ò Sọ Wípé Àmọ̀tẹ́kùn Ò B’ófinmu, Àwọn Ènìyàn Ló Ṣìmí Gbọ́ – Malami Kọ́rọ̀ Rẹ̀ Jẹ

YBTC Yoruba—Amòfin Àgbà ní orílẹ̀ èdè yìí tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́, ìyẹn Abubakar Malami ti sẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ́lẹ̀ rí wípé ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn tí àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ kò sí lábẹ́ òfin.

Malami ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè ní ilé iṣẹ́ rédíò ilẹ̀ Nàìjíríà l’Abuja ní òwúrọ̀ ọjọ́ ọjọ́bọ, ó sọ wípé ní ṣe ni àwọn ènìyàn ṣi ọ̀rọ̀ òun gbọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní àwọn ènìyàn ló ṣì ọ̀rọ̀ òun gbọ́, ó ní ǹkan tí òun sọ ni pé kí àwọn gómìnà náà fi òfin kín ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn lẹ́yìn kí àwọn ìjọba tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn má ba gba dànù nígbà tí kò bá sí lábẹ́ òfin.