Categories
Ìròyìn

Lórí Ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn, Igbá-kejì Ààrẹ àti Àwọn Gómìnà Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Wọlé Ìjíròrò

YBTC Yorùbá- Ìpàdé tí ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí láàrin Igbá-kejì Ààrẹ ilẹ̀ yìí, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo àti àwọn Gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ní olú ìlú wa l’Abuja

Ìdí ìpàdé náà kò dá lórí ọ̀rọ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn tí àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ǹkan bíi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn.

Agbẹjọ́rò Àgbà ní orílẹ̀ èdè yìí tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́, Abubakar Malami àti Ọ̀gá Ọlọ́pàá yányán ilẹ̀ yìí, Ọ̀gbẹ́ni Muhammed Adamu náà wà níbi ìpàdé náà.

Ṣáájú àsìkò yìí, oríṣiríṣi awuyewuye ni ó ti ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn.