Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àmọ̀tẹ́kùn Yóò Kùnà, Àyàfi… Tinubu Padà Sọ̀rọ̀ Lórí Àmọ̀tẹ́kùn, Kòní Óda Tàbí Kòda

YBTC Yorùbá- Ògbóntàrigì àgbàlagbà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) Asiwaju Bola Tinubu ti sọ wípé Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò ìyẹn Àmọ̀tẹ́kùn tí àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.

Tinubu ní èròǹgbà àwọn Gómìnà náà da bẹ́ẹ̀ sì ni ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ṣe kókó ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí èròǹgbà tí wọ́n ní fún Àmọ̀tẹ́kùn forí ṣọ́pọ́n tí wọn kò bá ṣe àtúnṣe àti àtúntò sí èròǹgbà náà.

Tinubu sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ọjọ́rú lẹ́yìn awuyewuye lóri dídá kẹ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn láti bíi ọjọ́ mélòó kan tí àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù náà tí ṣe ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò náà.

Tinubu bu ẹnu àtẹ lu àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn gúúsù ilẹ̀ yìí bí wọ́n ṣe ṣe ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn náà láì jẹ́ kí amòfin àgbà orílẹ̀ èdè yìí tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar Malami.

Bákan náà, ó sọ̀rọ̀ sí Malami bí ó ṣe bu ẹnu àtẹ lu ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn náà, ó ní ó yẹ kí Mínísítà náà kàn sí àwọn gómìnà náà, kí wọ́n sì yanjú ọ̀rọ̀ náà ní abẹ́lé.