Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àmọ̀tẹ́kùn: Àwa kò Kìí Ṣe Èèyàn Kéèyàn Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Orílẹ̀ Èdè Yìí – Fayemi

YBTC Yorùbá- Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì ti fi èsì sí ìròyìn wípé fífi lọ́lẹ̀ tí àwọn fi Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn lọ́lẹ̀ kìí ṣe fún ètò àtúntò tí àwọn kan ń pè fún tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n láti fi kún àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò ìjọba àpapọ̀ lápá.

Gómìnà náà níbi ìfilọ́lẹ̀ àwọn Ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn lánàá ọjọ́ ọjọ́bọ sọ wípé kí obìnrin ó rí ejò kí ó obìnrin kó pá, kí ọkùnrin kó rí ejò, kí ọkùnrin kó pá, ṣẹ̀ bí kí ejò ṣáà má ti lọ ni.

Láfikún, àwọn gómìnà náà ní Ààrẹ Muhammadu Buhari kò pé àwọn lórí ètò náà, bẹ́ẹ̀ni ó ṣàlàyé wípé ó ní ìdí tí àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ogun àti Osun kò fi sí níbi ètò ìfilọ́lẹ̀ náà.

Gómìnà ti ìpínlẹ̀ Ondo, Arákùnrin Rotimi Akeredolu sọ wípé àwọn gómìnà mẹ́ta náà kò lè yọjú síbi ìfilọ́lẹ̀ náà nítorí bí ojú ọjọ́ ṣe rí ní àsìkò náà.