Categories
Eré Ìdárayà

Ìròyìn Pàjáwìrì: Ikọ̀ West Ham United Ti Jáwèé Gbélé Ẹ Lé Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Wọn Lọ́wọ́

YBTC Yorùbá-Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú West Ham United ti jáwèé gbélé ẹ lé Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Manuel Pellegrini lọ́wọ́ lẹ́yìn tí Ikọ̀ ọ̀ún pàdánù nílé wọn sí ọwọ́ Ikọ̀ Leicester City.

Ayò Méjì sí oókan ni Ikọ̀ Leicester City fi bá West Ham United wí lẹ́yìn ìkùlé wọn nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn méjèèjì.

Ní kété tí ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ náà parí ni àwọn aláṣẹ Ikọ̀ West Ham United ní kí Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá náà lọ rọ́kúnlé.