Categories
Ìròyìn

Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Ilẹ̀ Nàìjíríà Ni Yóò Fa Ààrẹ Kalẹ̀ Ní Ọdún 2023 – Àgbàlagbà Nínú Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC

Alága àná tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, Olóyè Jide Awe ti sọ ní ọjọ́ àbàmẹ́ta wípé Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù ilẹ̀ yìí ni yóò fa Ààrẹ kalẹ̀ ní ọdún 2023 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC). Awe ní ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ gbóríyìn fún àwọn gómìnà ìwọ̀ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Tuntun Ti Ikọ̀ Barcelona Ní Òun Fẹ́ Kí Àwọn Agbábọ́ọ̀lù Òun Máa Gbá Bọ́ọ́lù T’ófanimọ́ra

YBTC Yorùbá-Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá tuntun ti Ikọ̀ Barcelona, ìyẹn Quique Setien ó ti sọ̀rọ̀ ìpeniníjà sí àwọn agbábọ́ọ̀lú Ikọ̀ náà láti máa gbá bọ́ọ́lù t’ófanimọ́ra, ó ní inú òun kò ní dùn, kódà tí wọ́n bá jáwe olúborí. Setien ni ó ma gbá ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ikọ̀ Granada ní ọlá tí ń ṣe ọjọ́ àìkú láti […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àpapọ̀ Ẹgbẹ́ Amòfin Ilẹ̀ Nàìjíríà Ti Bu Ẹnu Àtẹ Lu Amòfin Àgbà Ilẹ̀ Yìí Lóri Ipò Rẹ̀ Lórí Àmọ̀tẹ́kùn

YBTC Yorùbá- Àjọ ẹgbẹ́ àpapọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ yìí, ìyẹn Nigeria Bar Association (NBA) ti bu ẹnu àtẹ lu ọ̀rọ̀ tí amòfin àgbà ilẹ̀ yìí tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́, ìyẹn Abubakar Malami (SAN) sọ wípé ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn kò b’ófinmu. Àwọn Amòfin náà sọ̀rọ̀ yìí láti ẹnu agbẹnusọ gbogbogbò ẹgbẹ́ náà, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àwọn Ẹgbẹ́ Kan Ti Fún Tinubu Ní Wákàtí Méjìlélógún Láti Fi Ìpínnu Rẹ̀ Hàn Lórí Àmọ̀tẹ́kùn

YBTC Yorùbá-Àwọn ẹgbẹ́ kan ni Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà ti amọ̀sí Save Lagos Group ti fún Alága Abẹ́lé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Tinubu ni gbèdéke wákàtí méjìlélógún láti fi fi èrò rẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí Àmọ̀tẹ́kùn. Tinubu tí àwọn ènìyàn rí bi asíwájú ní Ìwọ̀ Oòrùn […]

Categories
Uncategorized

Ashley Young Fi Orílẹ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì Sílẹ̀, Ó Lọ Darapọ̀ Mọ́ Ikọ̀ Inter Milan Ní Orílẹ̀ Ìtàló

YBTC Yorùbá- Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú ti Inter Milan ní orílẹ̀ èdè Ìtàló lọ́ùń ti kéde ìfọwọ́bọ̀ ọmọ Ikọ̀ Manchester United, ìyẹn Ashley Young. Ọmọ ọdún Mẹ́rìlélọ́gbọ̀n naa darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ Inter Milan pelu Mílíọ̀nù kan olè díè owó ilẹ̀ Aláwọ̀ funfun pẹ̀lú adehun ọlọ́dún kan. Inú ọdún 2011 ni agbábọ́ọ̀lú Young darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ Manchester United […]

Categories
Ìròyìn

Afẹ́nifẹ́re Sọ Jágbajàgba Ọ̀rọ̀ Sí Malami, Wọ́n Ní Ọ̀rọ̀ Burúkú Ní Mínísítà Nsọ Nígboro Ẹnu

Ẹgbẹ́ ajá fún ẹ̀tọ́ ti àwọn Ọmọ Yorùbá tí a mọ̀ sí Afẹ́nifẹ́re ti sọ jágbajàgba ọ̀rọ̀ sì amòfin àgbà ilẹ̀ yìí tí ó tún jẹ́ Mínísítà fún ètò Ìdájọ́, ìyẹn Abubakar Malami (SAN) lórí ọ̀rọ̀ tí Mínísítà náà sọ wípé ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn kò b’ófinmu. Alága gbogbogbò ẹgbẹ́ gbẹ́ náà, Olóyè Olawale Oshun ní ọ̀rọ̀ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Arsenal Bu Iyì-Ẹ̀yẹ Fún Kanu Bí Ó Ṣe Pé Ọdún Mọ́kànlélógún Tí Ó Tọwọ́bọ̀wẹ́ Àdéhùn Pẹ̀lú Ikọ̀ Náà

YBTC Yoruba—Kanu Nwakwo tí ó dé adé agbábọ́ọ̀lú tó fakọyọ jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà ní ẹ̀meejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ikọ̀ Arsenal ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́ùń ti bu iyì-ẹ̀ye fún lánàá láti fi sààmì ọdún kankànlélógún tí agbábọ́ọ̀lú tí ó ti fẹ̀yìntì náà tọwọ́bọ̀wẹ́ àdéhùn pẹ̀lú Ikọ̀ náà. Àná ọjọ́ ọjọ́rú ní ópé ọdún kankànlélógún tí Ikọ̀ Arsenal […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Gómìnà Ilẹ̀ Yorùbá Ti Ń Gbìyànjú Láti Ṣe Ìpàdé Pò Pẹ̀lú Ààrẹ Buhari Lórí Ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

Alamí ti ń tó àwọn oníròyìn létí báyìí wípé àwọn Gómìnà ìwọ oòrùn gúúsù ti ń gbìyànjú láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari lóri bí ìjọba àpapọ̀ ṣe kéde Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn gẹ́gẹ́ bíi Ẹ̀ṣọ́ tí kò bófin mu. A gbọ́ wípé ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Buhari náà ma wáyé lèyín tí àwọn gómìnà náà […]

Categories
Ìròyìn

Wọ́n Búra Fún Uzodinma, Ó Bẹ̀rẹ̀ Síní Ṣe Ìwádìí Àwọn Gómìnà Mẹ́ta Tẹ́lẹ̀ Rìí Ní Ìpínlẹ̀ Imo

Àná òde yìí ni Adájọ́ àgbà ti ìpínlẹ̀ Imo ṣe ìbúra fún Gómìnà tí ilé Ẹjọ́ sọ pé òun ni ó jáwe olúborí nínú ìdìbò gbogbogbò lọ́dún tí ó kọjá. Ìyẹn Gómìnà Hope Uzodinma jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC). Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n ṣe ìbúra fún Gómìnà tuntun náà, ìyẹn Uzodinma ni ó […]

Categories
Eré Ìdárayà

Onazi Darapọ̀ Mọ́ Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Turkey, Denizlispor

YBTC Yorùbá- Agbábọ́ọ̀lù ipò àárín fún ikọ̀ Super Eagles ti ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn Ogenyi Onazi ti tọwọ́bọ̀wẹ́ àdéhùn ọlọ́dún kan àbọ̀ pẹ̀lú Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Turkey, ìyẹn Turkish Super Lig Club Denizlispor lẹ́yìn tí ó kúrò ní ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Trabzonspor. Onazi darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ Denizlispor láti Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú ti Ìtàló, ìyẹn Ikọ̀ Lazio ní oṣù […]