Categories
Eré Ìdárayà

Real Madrid Dáná Sun Barcelona Bí Ẹran Iléyá,Ojú Messi Pọ́n

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Spanish Laliga, Real Madrid àti Barcelona jọọ wàákò ní pápá ìṣeré Santiago Bernabeu fun ijakadi tani yóò lékè tábìlì. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Real Madrid to díyà jẹ Barcelona nínú ìdíje líìgì ni sáà yìí. Ní báyìí, Madrid ti bọ́ sí òkè téńté tábìlì, Atletico Madrid wà ní ipò […]

Categories
Eré Ìdárayà

Chelsea Pòkọ Ìyà Fún Crystal Palace, Liverpool Pa Aston Villa Lẹ́kún

YBTC News YORÙBÁ— Egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea kanra mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn, Crystal Palace, wọ́n lù wọ́n bíi bẹ̀ǹbẹ́ nàbíyù pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ẹ́rin sí ẹyọkan. Ami ayo meji kòǹgbà kòǹgbà ni Pulisic gbá wọlé kí Kurt Zouma àti Kai Havertz tóó gbá ayò kọ̀ọ̀kan wọlé. Liverpool bákan náà ẹ̀wẹ̀ fi àgbà hàn Aston Villa pẹ̀lú […]

Categories
Eré Ìdárayà

Leeds Utd Ká Man City Mọ́lé, Wọ́n Lù Wọ́n Bíi Bààrà

YBTC News YORÙBÁ—  Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Leeds United ti lọ bá Manchester City ní buba wọn, wọ́n lù wọ́n bíi bààrà lórí pápá ìṣeré wọn ní Etihad Ayò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni agbábọ́ọ̀lù Leeds United Stuart Dallas gbá wọlé Manchester City, pẹ̀lú bí adarí ìdíje náà ṣe lé L.cooper kúrò ní orí pápá nígbà tí ó kù […]

Categories
Ìròyìn

Orí Yọ Ọba Èkìtì Kan Bí Àwọn Agbébọn Ṣe Yìbọn Fún-un

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn Agbébọn kan ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ti yìbọn fún ọba alayé kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ọba Elewu ti Ewu Ekiti. Ọba Adétutù Àjàyí nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. Ọ̀nà ayetoro-Ewu ni ọba Adétutù ń lọ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje. Eléyìí ṣẹlẹ̀ kò tíì ju ọjọ́ kan lọ tí àwọn agbébọn bákan náà […]

Categories
Ìròyìn

Ìjọba Àpapọ̀ Tún Ti Sèètò Àwọn Ọkọ̀ Ojú-irin Tuntun. Ẹ Wo Ìlú Tí Wọ́n Wà

YBTC News YORÙBÁ— Mínísítà tí ó ń rí sí ètò ìrìnà ní orílẹ-èdè Nàíjíríà, Rotimi Amaechi ti kéde ní àná ọjọ́ Àbámẹ́ta wípé ìjọba àpapọ̀ ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe okọ̀ ojú-irin mẹ́ẹ́rin tuntun. Amaechi sọ èyí nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní Àbújá. Lára àwọn àyè tí wọn yóò ṣe àwọn ọkọ̀ ojú […]

Categories
Ìròyìn

Àmọ̀tẹ́kùn Àti Miyetti Allah Ṣe Ìpàdé Ní Ọ̀sun. Ẹ Wo Àbájáde Ìpàdé

YBTC News YORÙBÁ— Ẹ̀ṣọ́ àbò ilẹ̀ Yorùbá, Àmọ̀tẹ́kùn ti ẹka ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ìròyìn ti gbé e wípé wọ́n jọ ń ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Miyetti Allah fún bí ètò ọrọ̀ àbò ìpínlẹ̀ náà yóò ṣe dára. Àwọn àkójọpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá kan tí wọn pè ní “Kiriji Heritage” to fi ẹ̀hónú ọkàn wọn lánàá […]

Categories
Ìròyìn

Ọlọ́pàá Ti Mú Àwọn Méjì Fún Gbígbé Ewúrẹ́ Mẹ́wàá Ní Èkìtì

YBTC News YORÙBÁ—  Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Èkìtì ti fi páńpẹ́ òfin mú àwọn afurasí méjì kan pẹ̀lú bí wọ́n ṣe bá àwọn ewúrẹ́ mẹ́wàá tí wọ́n wá kiri ní àkàtà wọn ní Igbemọ-Ekìtì ní ìjọba ìbílẹ̀ Ireposun/Ifelodun. Mr Sunday Abutu, agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, nígbà tí ó ń […]

Categories
Ìròyìn

WAEC Ti Kéde Ọjọ́ Tí Ìdánwò Yóò Bẹ̀rẹ̀. Ẹ Wo Ọjọ́ Náà

YBTC News YORÙBÁ— Àjọ tí ó ń rísí ìdánwò fún àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìhà ìwọ̀-oòrùn adúláwọ̀ WAEC, ti kéde pé ìdánwò yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ títí di ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹẹ̀sán, 2021. Ẹ rántí wípé adarí àjọ náà, Patrick Areghan tí sọ tẹ́lẹ̀ wípé ó ṣe é ṣe kí ìdánwò WAEC tí […]

Categories
Ìròyìn

El-Rufai Sọ Pé Tí Àwọn Ajínigbé Bá Gbé Ọmọ Òun Gan, Òun Ò Ní Sanwó

YBTC News YORÙBÁ— Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam El-Rufai sọ pé òun kò níí san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé kódà tí wọn bá gbé ọmọ bíbí inú òun. El-Rufai sọ èyí di mímọ̀ nínú ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ lórí rẹ́díò ní òní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìṣèjọba òun kò fi àyè sílẹ̀ fún […]

Categories
Ìròyìn

Buhari Yan Oyegun Gẹ́gẹ́ Bí Alága Ìgbìmọ̀ UI

YBTC News YORÙBÁ—  Ààrẹ Buhari ti yan alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC nígbàkan rí, John Oyegun gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ ilé ìwé gíga UI ní Ìbàdàn. Yàtọ̀ sí ilé ìwé UI, àwọn ilé ìwé gíga mìíràn tí ààrẹ Buhari tún yẹn àwọn ìgbìmọ̀ fún ni Yunifásítì Port Harcourt (UNIPORT), Yunifásítì Èkó (UNILAG). Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (OAU), Ile-Ife, […]